Hymn 467 – OHUN ogo Re l'a n royin | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OHUN ogo Re l'a n royin" (C&S Hymn #467, Yoruba). OHUN ogo Rẹ l'a ń royin, Sion, ti Ọlọrun wa: Ọrọ ẹni t'a ko le yẹ,…

Hymn 467 – OHUN ogo Re l'a n royin | C&S Yoruba Hymnary
OHUN ogo Rẹ l'a ń royin, Sion, ti Ọlọrun wa: Ọrọ ẹni t'a ko le yẹ, Se o yẹ fun 'bugbe Rẹ, L'ori apat' ayérayé, Kini le mi 'sinmi rẹ? A f'odi 'gbala yi ọ ka, K'o le ma rin ọta rẹ. Wo! ipado omi iye, Nt' ifẹ Ọlọrun sun wa, O to fun gbogbo Ọmọ rẹ, Ẹru aini ko si mọ; Tal'o le re, 'gba odo na, Ba ń san t'o le poungbẹ rẹ? Or'ọfẹ Olodumare, Ki yẹ lat' irandiran. Ara Sion alabukun, T'o f'ẹjẹ Oluwa wẹ; Jesu ti wọn ti ń gbẹkẹle, Sọ wọn d'Ọba, woli Rẹ, Sisa l'ohun afẹ ayé, Pẹlu ogo asan rẹ Isura totọ at'ayọ, Kik' ọmọ Sion l'o mọ. AMIN

Hymn 467 – OHUN ogo Re l'a n royin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia