Hymn 470 – OM'OLORUN a ko ri O | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OM'OLORUN a ko ri O" (C&S Hymn #470, Yoruba). ỌM'ỌLỌRUN a ko ri Ọ, 'Gba t'o wa s'ayé iku yi; Awa ko ri ibugbe Rẹ, Ni…

Hymn 470 – OM'OLORUN a ko ri O | C&S Yoruba Hymnary
ỌM'ỌLỌRUN a ko ri Ọ, 'Gba t'o wa s'ayé iku yi; Awa ko ri ibugbe Rẹ, Ni Nasareti ti a gan; Sugbọn a gbagbọ p'esẹ Rẹ, Ti tẹ ita rẹ kakiri. A ko ri Ọ lori igi, T'eniyan buburu kan Ọ mọ, A ko gbọ igbe Rẹ, wi pé, Dariji won, tor' aimọ wọn Sibẹ, a gbagbọ pe, 'ku Rẹ Mi ayé, o si m'orun su. A ko duro leti boji, Nibi ti a gbe tẹ Ọ si; A ko joko 'nu yara ni, A ko ri Ọ loju ọna, Sugbọn a gbagbọ p'angeli Wi pé, ―Iwọ ti ji dide. A ko r'awọn wọnni t'o yan, Lati ri 'goke r'orun Rẹ; Wọn ko fi iyanu woke, Wọn si f'ẹru dojubolẹ, Sugbọn a gbagbọ pe wọn ri Ọ, Bi O ti n goke lọ s'ọrun. Iwọ n jọba l'oke loni, 'Wọ si n bukun awọn Tire, Imọlẹ ogo Rẹ ko tan, Si aginju ayé wa yi, Sugbọn, a gba ọrọ Rẹ gbọ, Jesu, Olurapada wa. AMIN

Hymn 470 – OM'OLORUN a ko ri O | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia