Hymn 454 – KO to k'awon mimo b)eru | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KO to k'awon mimo b)eru" (C&S Hymn #454, Yoruba). KO tọ k'awọn mimọ bẹru, Ki wọn sọ'reti nu; 'Gba wọn ko reti 'ranwọ…
KO tọ k'awọn mimọ bẹru, Ki wọn sọ'reti nu; 'Gba wọn ko reti 'ranwọ Rẹ, Olugbala y'o de. Ka d'amure lati jagun (2) Ka d'amure e (2) Ka d'amure lati jagun. Nigba ti Abram mu ọbẹ, Ọlọrun ni ―Duro‖; Agbo ti o wa lọhun ni, Y'o dipo ọmọ na. Ka d'amure lati jagun (2) Ka d'amure e (2) Ka d'amure lati jagun. 'Gba Jona ri sinu omi, Ko ro lati yọ mọ; Sugbọn Ọlọrun ran ẹja, T 'o gbe lọ s'ebute. Ka d'amure lati jagun (2) Ka d'amure e (2) Ka d'amure lati jagun. B'iru ipa at'ifẹ yi, Ti pọ l'ọrọ Rẹ to; Emi ba ma k'aniyan mi, Le Oluwa lọwọ. Ka d'amure lati jagun (2) Ka d'amure e (2) Ka d'amure lati jagun. Ẹ duro de iranwọ Rẹ, B'o tilẹ pẹ, duro; B'ileri na tilẹ fa'lẹ Sugbọn ko le pẹ de. Ka d'amure lati jagun (2) Ka d'amure e (2) Ka d'amure lati jagun. AMIN Ka d'amure lati jagun (2) Ka d'amure e (2) Ka d'amure lati jagun.
Hymn 454 – KO to k'awon mimo b)eru | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia