Hymn 455 – KO to k'awon mimo beru | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KO to k'awon mimo beru" (C&S Hymn #455, Yoruba). KO tọ k'awọn mimọ bẹru, Ki wọn sọ 'reti nu; 'Gba wọn ko reti 'ranwọ…

Hymn 455 – KO to k'awon mimo beru | C&S Yoruba Hymnary
KO tọ k'awọn mimọ bẹru, Ki wọn sọ 'reti nu; 'Gba wọn ko reti 'ranwọ Rẹ Olugbala y'o de. Jesu mbọ (3) Ẹyin Ọmọ Ogun, Ẹ damure giri. Nigba ti Abram mu ọbẹ, Ọlọrun ni ―Duro; Agbo ti o wa lọhun ni, Y'o dipo ọmọ na. Jesu mbọ (3) Ẹyin Ọmọ Ogun, Ẹ damure giri. 'Gba Jona ri sinu omi, Ko ro lati yọ mọ; Sugbọn Ọlọrun ran ẹja, T 'o gbe lọ s'ebute. Jesu mbọ (3) Ẹyin Ọmọ Ogun, Ẹ damure giri. B'iru ipa at' ifẹ yi, Ti pọ l'ọrọ Rẹ to! Emi ba ma k'aniyan mi, Le Oluwa lọwọ. Jesu mbọ (3) Ẹyin Ọmọ Ogun, Ẹ damure giri. Ẹ duro de iranwọ Rẹ, B'o tilẹ pẹ, duro; B'ileri naa tilẹ falẹ Sugbọn ko le pẹ de. Jesu mbọ (3) Ẹyin Ọmọ Ogun, Ẹ damure giri. AMIN Jesu mbọ (3) Ẹyin Ọmọ Ogun, Ẹ damure giri.

Hymn 455 – KO to k'awon mimo beru | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia