Hymn 453 – JESU, Olugbala, wo mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, Olugbala, wo mi" (C&S Hymn #453, Yoruba). JESU, Olugbala, wo mi, Arẹ mu mi, ara n ni mi: Mo de lati wa gb'ara le…
JESU, Olugbala, wo mi, Arẹ mu mi, ara n ni mi: Mo de lati wa gb'ara le Ọ, 'Wọ 'sinmi mi. Boju wo mi, o rẹ mi tan; Irin ajo naa gun fun mi; Mo n wa 'ranwọ agbara Rẹ, 'Wọ Ipa mi. Idamu ba mi lọna mi, Oru sokun, iji si ń fẹ, Tan imọlẹ si ọna mi, 'Wọ 'Mọlẹ mi. Gba Satani ba tafa rẹ, 'Wọ ni mo n wo; n ko bẹru mọ, Agbelebu Rẹ l'abo mi, 'Wọ Alafia mi. Mo nikan wa leti Jọrdan, Ninu 'waya-'ja jelo ni: 'Wọ ki yoo jẹ k'emi ri, 'Wọ Iye mi. Gbogbo aini, 'Wọ o fun mi, Titi d'opin; l'ọnakọna; Ni 'ye, ni 'ku, titi lailai, 'Wọ gbogbo mi. AMIN
Hymn 453 – JESU, Olugbala, wo mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia