Hymn 452 – Jesu l'Olusaguntan mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Jesu l'Olusaguntan mi" (C&S Hymn #452, Yoruba). Jesu l'Olusaguntan mi, Ọrẹ ẹni ti ki yẹ! Ko s'ewu bi mo jẹ Tirẹ, T'O…
Jesu l'Olusaguntan mi, Ọrẹ ẹni ti ki yẹ! Ko s'ewu bi mo jẹ Tirẹ, T'O si jẹ temi titi. Nib' odo omi iye ń san, Nibẹ, l'o ń m'ọkan mi lọ; Nibi ti oko tutu ń hu, L'o ń f'Ounjẹ ọrun bọ mi. Mo ti fi were sako lọ, N'ifẹ O si wa mi ri; L'ejika Rẹ l'o gbe mi si, O f'ayọ mu mi wa 'le. N ko bẹru ojiji iku, B'Iwọ ba wa lọdọ mi; Ọgọ Rẹ ati Ọpa Rẹ, Awọn l'o ń tu mi ninu. Iwọ tẹ tabili fun mi; 'Wọ d'ororo sori mi; A! ayọ na ha ti pọ to! Ti ń t'ọdọ Rẹ wa ba mi. Bẹ lọjọ ayé mi gbogbo Ore Rẹ ki o yẹ lai; Olusaguntan, n ó yin Ọ, Ninu ile Rẹ titi. AMIN
Hymn 452 – Jesu l'Olusaguntan mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia