Hymn 045 – MO n toro nkan lodo Kristi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MO n toro nkan lodo Kristi" (C&S Hymn #045, Yoruba). 1. MO n tọrọ nkan lọdọ Kristi, 'Tori ẹrẹ pọ lọna mi, Yala pe…

Hymn 045 – MO n toro nkan lodo Kristi | C&S Yoruba Hymnary
1. MO n tọrọ nkan lọdọ Kristi, 'Tori ẹrẹ pọ lọna mi, Yala pe l'omi tab'ina, Sa wẹ mi mọ, sa wẹ mi mọ. Jọ, wẹ mi mọ t'ara t'ọkan N ó kọ ina bo ba gba bẹẹ Ọna-kọna lo dun mọ mi, K'ẹsẹ sa ku 'nu ọkan mi. 2. B'o ba f'iran didan han mi, N ó dupẹ inu mi yoo dun; Sugbọn ọkan t'o mọ gara, Ni mo fẹ ju, ni mo fẹ ju. 3. Nigba ti ọkan mi ba mọ, Iran didan yoo han si mi; Nitori okunkun su bo, Iran ọrun, iran ọrun. 4. Mo n du ki n sa f'ọna ẹsẹ, Ki n si yago f'ero ẹsẹ, B'ijakadi mi ti to yi, Sibẹ n ko mọ, sibẹ n ko mọ. Jọ, wẹ mi mọ t'ara t'ọkan N ó kọ ina bo ba gba bẹ Ọna-kọna lo dun mọ mi, K'ẹsẹ sa ku 'nu ọkan mi. AMIN

Hymn 045 – MO n toro nkan lodo Kristi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia