Hymn 044 – OJO isinmi Olorun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO isinmi Olorun" (C&S Hymn #044, Yoruba). 1. ỌJỌ isinmi Ọlọrun, Ọjọ ti o dara julọ; Ti Ọlọrun ti fun wa, K'awa ko…

Hymn 044 – OJO isinmi Olorun | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌJỌ isinmi Ọlọrun, Ọjọ ti o dara julọ; Ti Ọlọrun ti fun wa, K'awa ko sinmi ninu rẹ. 2. Ọjọ mẹfa l'O fi fun wa, K'a fi se isẹ wa gbogbo; Sugbọn ọjọ keje yatọ, Ọjọ 'sinmi Ọlọrun ni. 3. K'a fi'sẹ asan wa, silẹ, Ti awa n se n'ijọ mẹfa; Mimọ ni isẹ ti oni, Ti Ọlọrun Oluwa wa. 4. A pada de nisinsin yii, Ninu ile Ọlọrun wa; Jẹ k'a kọrin didun si I, Ni owurọ ọjọ oni. 5. Ni kutukutu 'jọ keje, Ni ọjọ isinmi mimọ; Jẹ k'a jumọ kọrin didun, Jẹ k'a si jumọ gbadura.

Hymn 044 – OJO isinmi Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia