Hymn 046 – GB'ADURA wa, Oba aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GB'ADURA wa, Oba aye" (C&S Hymn #046, Yoruba). 1. GB'ADURA wa, Ọba ayé, 'Gba t'a wolẹ fun Ọ, Gbogbo wa n kigbe…

Hymn 046 – GB'ADURA wa, Oba aye | C&S Yoruba Hymnary
1. GB'ADURA wa, Ọba ayé, 'Gba t'a wolẹ fun Ọ, Gbogbo wa n kigbe n'irẹlẹ, A mbẹbẹ fun anu Tiwa l'ẹbi, tirẹ l'aanu Mase le wa pada, Sugbọn gbọ'gbe wa n'itẹ Rẹ Ran adura wa lọwọ. 2. Ẹsẹ awọn baba wa pọ, Tiwa ko si kere, Sugbọn lati irandiran, Lo ti f'ore Rẹ han, Nigba ewu, b'omi jija Yi ilu wa yi ka, Iwọ la n wo ta si n ke pe, K'a ma r‘iranwọ Rẹ. 3. L'ohun kan gbogbo wa wolẹ, L'abẹ iyọnu Rẹ, Gbogbo wa n jẹwọ ẹsẹ wa, A n gbawẹ fun 'le wa, F'oju anu wo aini wa, Bi a ti n ke pe Ọ! Ma fi'dajọ Rẹ ba wa wi, Da wa si laanu Rẹ. AMIN

Hymn 046 – GB'ADURA wa, Oba aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia