Hymn 415 – WAKATI adura didun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WAKATI adura didun" (C&S Hymn #415, Yoruba). WAKATI adura didun! T'o gbe mi lọ kuro l'ayé, Lọ 'waju itẹ Baba mi, Ki n…

Hymn 415 – WAKATI adura didun | C&S Yoruba Hymnary
WAKATI adura didun! T'o gbe mi lọ kuro l'ayé, Lọ 'waju itẹ Baba mi, Ki n sọ gbogbo ẹdun mi fun; Nigba 'banujẹ at'aro, Adua l'abo fun ọkan mi: Emi si bọ lọwọ Esu, 'Gbati mo ba gb'adua didun Emi si bọ lọwọ Esu, 'Gbati mo ba gb'adua didun Wakati adura didun! Iyẹ rẹ y'o gbe ẹbẹ mi, Lọ sọd' Ẹni t'o se 'leri, Lati bukun ọkan adua: B'O ti kọ mi, ki n woju Rẹ, Ki n gbẹkẹle, ki n si gb' gbọ: N ó ko gbogb' aniyan mi le, Ni akoko adua didun, N ó ko gbogb' aniyan mi le, Ni akoko adua didun. Wakati adura didun! Jẹ ki n ma r'itunu rẹ gba, Titi n ó fi d'oke Pisga, Ti n ó r'ile mi l'okere, N ó bo agọ ara silẹ, N ó gba ere ainipẹkun: N ó kọrin bi mo ti n fo lọ, O digbose! Adua didun, N ó kọrin bi mo ti n fo lọ, O digbose! adua didun. AMIN

Hymn 415 – WAKATI adura didun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia