Hymn 414 – JESU lo n gbebi aboyun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU lo n gbebi aboyun" (C&S Hymn #414, Yoruba). JESU lo n gbẹbi aboyun, Ẹ mase jẹ k'a foya, Olugbala wa ni Jesu, Ẹ…
JESU lo n gbẹbi aboyun, Ẹ mase jẹ k'a foya, Olugbala wa ni Jesu, Ẹ mase jẹ k'a foya. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Ẹyin aboyun Séráfù, Ẹ ke pe Jesu nikan, K'ẹ si gbẹkẹ yin le pẹlu, Y'o da yin silẹ l'ayọ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Olugbala, 'Wọ ti 'ya Rẹ, Ru Ọ gba osu mẹsan; Ni Bethlehem Judea, Layọ ibi sọkalẹ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Ki l'ohun ti mba yin l'ẹru, Ẹyin ọmọ ogun Kristi, 'Gbati Jesu ti jẹ tiwa, Ayọ ni yoo jẹ tiwa Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Lọwọ ajẹ ati oso, Lọwọ ajakalẹ arun, Lọwọ iku, ẹkun, ose Jesu yoo pa Tirẹ mọ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Mẹtalọkan Alagbara, Dabobo awọn ọmọ Rẹ, Lọwọ ọta ati esu, Jẹ kawa k'Alleluyah. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Ọlọrun to l'agan ninu, Y'o gbọ t'ẹyin ti n tọrọ, B'O ti s'ẹkun Hannah d'ẹrin, Yo f'ọmọ pa yin l'ẹrin. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. Ogo ni fun Baba l'oke, Ogo ni fun Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan l'ọpẹ yẹ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ. AMIN Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu ni Ọba wa, B'o ti wu k'iji na le to, Y'o da wa silẹ layọ.
Hymn 414 – JESU lo n gbebi aboyun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia