Hymn 416 – OLUWA, a wa 'do Re | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA, a wa 'do Re" (C&S Hymn #416, Yoruba). OLUWA, a wa 'dọ Rẹ, L'ẹsẹ Rẹ l'a kunlẹ si; A! ma kẹgan ẹbẹ wa, A o wa Ọ…

Hymn 416 – OLUWA, a wa 'do Re | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA, a wa 'dọ Rẹ, L'ẹsẹ Rẹ l'a kunlẹ si; A! ma kẹgan ẹbẹ wa, A o wa Ọ lasan bi? L'ọna ti O yan fun wa L'a n wa Ọ lọwọlọwọ: Oluwa, a ki o lọ, Titi 'Wọ o bukun wa. Ransẹ lat'ọrọ Rẹ wa, Ti O fi ayọ fun wa; Jẹ ki emi Rẹ ko fun Ọkan wa ni igbala. Jẹ k'a wa, k'a si ri Ọ Ni Ọlọrun Olore, p W'alaisan, da' 'gbekun si, Ki gbogbo wa yọ si Ọ. AMIN

Hymn 416 – OLUWA, a wa 'do Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia