Hymn 041 – EMI Olorun alaye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EMI Olorun alaye" (C&S Hymn #041, Yoruba). 1. ẸMI Ọlọrun alaye, N'nu ẹkun ore-ọfẹ Rẹ, Nibi t'ẹsẹ eniyan ti tẹ, Sọkalẹ…
1. ẸMI Ọlọrun alaye, N'nu ẹkun ore-ọfẹ Rẹ, Nibi t'ẹsẹ eniyan ti tẹ, Sọkalẹ sori iran wa. 2. F'ẹbun ahọn, ọkan ifẹ, Fun wa lati sọrọ 'fẹ Rẹ, K'ibukun at'agbara Rẹ, Ba l'awọn t'o n gbọ ọrọ naa. 3. K'ookun kasẹ ni bibọ Rẹ; Ki darudapọ di tito; F'ilera f'ọkan ailera; Jẹ ki aanu bori ibinu. 4. Ẹmi Ọlọrun, jọ pese Gbogbo ayé fun Oluwa; Mi si wọn b'afẹfẹ oorọ, K'ọkan okuta le sọji. 5. Baptis' gbogb' orilẹ-ede, Royin 'sẹgun Jesu yika; Yin orukọ Jesu logo, Tit' arayé yoo jẹwọ Rẹ. AMIN
Hymn 041 – EMI Olorun alaye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia