Hymn 040 – AYO l'ojo 'sinmi fun mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AYO l'ojo 'sinmi fun mi" (C&S Hymn #040, Yoruba). 1. AYỌ l'ọjọ 'sinmi fun mi, Ati agogo at'iwasu; 'Gba t'a ba mi n'nu…
1. AYỌ l'ọjọ 'sinmi fun mi, Ati agogo at'iwasu; 'Gba t'a ba mi n'nu 'banujẹ, mf Awọn l'o n mu inu mi dun. 2. Ayọ si ni wakati naa, Ti mo lo n'nu agbala Rẹ; Lati mọ adun adura, Lati gba manna ọrọ Rẹ. 3. f Ayọ ni idahun ―Ami To gba gbogbo ile naa kan, Lẹẹkọọkan l'o n dun, t'o n rọlẹ, O n kọja lọ s'ọdọ Baba. 4. B'ayé fẹ f'agbara de mi Mọ isẹ ọjọ mẹfa rẹ; Oluwa, jọ tu ide na, K'O sọ ọkan mi d'ominira. AMIN
Hymn 040 – AYO l'ojo 'sinmi fun mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia