Hymn 409 – NINU gbogbo iji ti ń ja | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NINU gbogbo iji ti ń ja" (C&S Hymn #409, Yoruba). NINU gbogbo iji ti ń ja Ninu gbogbo igbi 'pọnju, Abo kan mbẹ ti o…

Hymn 409 – NINU gbogbo iji ti ń ja | C&S Yoruba Hymnary
NINU gbogbo iji ti ń ja Ninu gbogbo igbi 'pọnju, Abo kan mbẹ ti o daju, O wa labẹ itẹ-anu, Ibi kan wa ti Jesu n da, Ororo ayọ sori wa, O dun ju ibi gbogbo lọ, Itẹ anu t'a f'ẹjẹ wọn. Ibi kan wa fun idapọ, Nibi ọrẹ n pade ọrẹ, Lairi 'ra nipa igbagbọ, Wọn y'itẹ-anu kan naa ka. A! nibo ni a ba sa si, Nigba 'danwo at'ipọnju? A ba se le bori esu, B'o se pe ko si 'tẹ-anu? A! bi idi l'a fo sibẹ, B'ẹni pe ayé ko si mọ; Ọrun wa pade ọkan wa. Ogo si bo itẹ-anu. AMIN

Hymn 409 – NINU gbogbo iji ti ń ja | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia