Hymn 410 – OJU kan mbẹ ti ki togbe | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJU kan mbẹ ti ki togbe" (C&S Hymn #410, Yoruba). OJU kan mbẹ ti ki togbe, Nigba t'ilẹ ba su; Eti kan mbẹ ti ki ise,…

Hymn 410 – OJU kan mbẹ ti ki togbe | C&S Yoruba Hymnary
OJU kan mbẹ ti ki togbe, Nigba t'ilẹ ba su; Eti kan mbẹ ti ki ise, 'Gbati orun ba wọ. Apa kan mbẹ ti ko le rẹ, 'Gbat 'pa eniyan pin; Ifẹ kan mbẹ ti ko le ku, 'Gba 'fẹ ayé ba ku. Oju na n wo awọn Séráfù, Apa naa d'ọrun mu; Eti na kun f'orin Angel, Ifẹ naa ga loke. Ipa kan l'eniyan lo, 'Gba t'ipa gbogbo pin; Lati ri oju at'apa, Ati ifẹ nla na. Ipa naa ni adura wa, Ti n lo 'waju itẹ; f To n mi ọwọ t'o s'ayé ro, Lati mu 'gbala wa. Iwọ t'anu Rẹ ko lopin; T'ifẹ Rẹ ko le ku: Jẹ k'a n'igbagbọ at'ifẹ, K'a le ma gbadura. AMIN

Hymn 410 – OJU kan mbẹ ti ki togbe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia