Hymn 408 – BABA orun, nin' oro Re | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "BABA orun, nin' oro Re" (C&S Hymn #408, Yoruba). BABA ọrun, nin' ọrọ Rẹ, Ni ogo ọrun n tan; Titi lai l'a o ma yin Ọ,…

Hymn 408 – BABA orun, nin' oro Re | C&S Yoruba Hymnary
BABA ọrun, nin' ọrọ Rẹ, Ni ogo ọrun n tan; Titi lai l'a o ma yin Ọ, Fun Bibeli mimọ. Ọpọ 'tunu wa ninu rẹ, Fun ọkan alarẹ; Gbogbo ọkan ti oungbẹ n gbẹ, N ri omi iye mu. Ninu rẹ l'alafia wa, Ti Jesu fi fun wa; Iye ainipẹkun si wa, N'nu rẹ fun gbogbo wa. Iba le ma jẹ ayọ mi, Lati ma ka titi; Ki n ma ri ọgbọn titun kọ, N'nu rẹ lojojumọ. Oluwa Olukọ ọrun, Mase jina si mi; Kọ mi lati fẹ ọrọ Rẹ, Ki n ri Jesu nibẹ. AMIN

Hymn 408 – BABA orun, nin' oro Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia