Hymn 407 – BABA anu, n'nu oro Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA anu, n'nu oro Re" (C&S Hymn #407, Yoruba). BABA anu, n'nu ọrọ Rẹ, L'ogo ailopin n tan; K'a ma yin orukọ Rẹ lai,…
BABA anu, n'nu ọrọ Rẹ, L'ogo ailopin n tan; K'a ma yin orukọ Rẹ lai, Fun iwe mimọ yi. N'nu rẹ l'awọn alaini le Ri ọrọ ailopin; Ọrọ, t'ayé ko le fun-ni, T'o daju bi iye. N'nu rẹ n'igi imọ rere, N fun-ni l'Ounjẹ ọfẹ, T'adun rẹ po ju t'ayé lọ, T'o n fa gbogbo ẹda. N'nu rẹ l'a gbọ t'Oludande, N kede alafia; Iro didun na jẹ iye, At'ayọ ailopin. Oluwa, Olukọ mimọ, Ma sunmọ mi titi, Kọ mi lati fẹ ọrọ Rẹ, Ki n ri Jesu nibẹ. AMIN
Hymn 407 – BABA anu, n'nu oro Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia