Hymn 403 – Ro mo Bibeli! b'a gb'awon n kan 'yoku | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Ro mo Bibeli! b'a gb'awon n kan 'yoku" (C&S Hymn #403, Yoruba). Rọ mọ Bibeli! b'a gb'awọn n kan 'yoku, Ma sọ ilana rẹ…

Hymn 403 – Ro mo Bibeli! b'a gb'awon n kan 'yoku | C&S Yoruba Hymnary
Rọ mọ Bibeli! b'a gb'awọn n kan 'yoku, Ma sọ ilana rẹ t'o sọwọn nu; Ihin rẹ n ji gbogbo ọkan ti n togbe, Ileri Rẹ n sọ oku d'alaye. Ro mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! 'mọlẹ f'ẹsẹ wa. Rọ mọ Bibeli! Ọrọ 'yebiye yi, O n fi 'ye ainipẹkun f'arayé; O ni 'ye lori ju b'ẹda ti ro lọ, Wa ibukun Rẹ nigba t'a le ri! Ro mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! 'mọlẹ f'ẹsẹ wa. Fitila f'ẹni ti o ti sako lọ, Amọna fun Ọdọ ti 'ba subu; 'Reti ẹlẹsẹ t'ayé rẹ ti bajẹ, Ọpa f'agba, Iwe didara julọ! Rọ mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! 'mọlẹ f'ẹsẹ wa. AMIN Rọ mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! Rọ mọ Bibeli! 'mọlẹ f'ẹsẹ wa.

Hymn 403 – Ro mo Bibeli! b'a gb'awon n kan 'yoku | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia