Hymn 402 – Tori Mi at'Ihinrere | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Tori Mi at'Ihinrere" (C&S Hymn #402, Yoruba). Tori Mi at'Ihinrere, Ẹ lọ sọ t'irapada; Awọn onsẹ Rẹ n ke, 'Amin'! Tirẹ…

Hymn 402 – Tori Mi at'Ihinrere | C&S Yoruba Hymnary
Tori Mi at'Ihinrere, Ẹ lọ sọ t'irapada; Awọn onsẹ Rẹ n ke, 'Amin'! Tirẹ ni gbogbo ogo, Wọn n sọ t'ibi, t'iya, t'iku Ifẹ etutu nla Rẹ; Wọn ka ohun ayé s'ofo T'ajinde oun 'jọba Rẹ. Gbọ, gbọ ipe ti Jubili, O n dun yi gbogbo ayé ka; N'ile ati l'oju okun, A n tan ihin igbala, Bi ọjọ na ti n sunmọ'le, T'ogun si n gbona janjan, Imọlẹ Ila-orun na, Y'o mọ larin okunkun. Siwaju ati siwaju, La o ma gbọ Halleluyah, Ijọ ajagun y'o ma yọ, Pẹl' awọn oku mimọ; A fọ asọ wọn n'nu ẹjẹ, Duru wura wọn si n dun; Ayé at'ọrun d'ohun pọ, Wọn n kọ orin isẹgun. O de, Ẹni t'a n w'ọna Rẹ, Ẹni ikẹhin na de, Immanueli t'o d'ade, Oluwa awọn mimọ, Iye, Imọlẹ at'Ifẹ, Mẹtalọkan titi lai; Tirẹ ni Itẹ Ọlọrun, Ati t'Ọda-aguntan. AMIN

Hymn 402 – Tori Mi at'Ihinrere | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia