Hymn 401 – Emi Mimo , mi s'okan wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Emi Mimo , mi s'okan wa" (C&S Hymn #401, Yoruba). Ẹmi Mimọ , mi s'ọkan wa, K'a mọ agbara Rẹ, Orisun emi 'sọtẹlẹ,…
Ẹmi Mimọ , mi s'ọkan wa, K'a mọ agbara Rẹ, Orisun emi 'sọtẹlẹ, T'imọlẹ at'ifẹ. Ẹmi Mimọ, l'agbara Rẹ, L'awọn woli sise; Iwọ l'o n fi otọ han wa, Ninu iwe mimọ. Adaba ọrun, na 'yẹ Rẹ, Bọ okun ẹda wa; Jẹ ki 'mọlẹ Rẹ tan sori, Ẹmi aisotọ wa. A o mo Ọlọrun daju, B'Iwọ ba mbẹ n'nu wa, A o mo 'jinlẹ ifẹ mimọ, Pẹlu awọn Tirẹ. AMIN
Hymn 401 – Emi Mimo , mi s'okan wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia