Hymn 386 – 'GBANI t'Olorun sokale | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'GBANI t'Olorun sokale" (C&S Hymn #386, Yoruba). 'GBANI t'Ọlọrun sọkalẹ; O wa ni ibinu; Ara si ń san niwaju Rẹ.…

Hymn 386 – 'GBANI t'Olorun sokale | C&S Yoruba Hymnary
'GBANI t'Ọlọrun sọkalẹ; O wa ni ibinu; Ara si ń san niwaju Rẹ. Okunkun oun ina. Nigba t'o wa nigba keji, O wa ninu ifẹ; Ẹmi Rẹ si ń tu ni lara, B'afẹfẹ owurọ. Ina Sinai ijọ kini, T'ọwọ re mbu soke, Sọkalẹ jẹjẹ bi ade, Si ori gbogbo wọn. Bi ohun ẹru na ti dun Leti Israeli, Ti wọn si gbọ iro ipe T'o m'ohun angẹli gbọn. Be gẹgẹ nigba t'Ẹmi wa, Ba le awọn Tirẹ; Iro kan si ti ọrun wa, Iro iji lile. O ń kun, Ijọ Jesu, o ń kun Ayé ẹsẹ yika; L'o kan alaigbọran nikan, Ni aye ko si fun. Wa, Ọgbọn, ifẹ, at'Ipa, Mu ki eti wa si; K'a ma sọ akoko wa nu; Ki 'fẹ Rẹ le gba wa. AMIN

Hymn 386 – 'GBANI t'Olorun sokale | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia