Hymn 387 – Olurapada ikehin | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Olurapada ikehin" (C&S Hymn #387, Yoruba). Olurapada ikẹhin, Dagbere ikẹhin, O fi olutunu fun ni, Ti mba wa gbe. O wa…
Olurapada ikẹhin, Dagbere ikẹhin, O fi olutunu fun ni, Ti mba wa gbe. O wa ni awọ adaba, O na iyẹ bo wa; O tan 'fẹ oun alafia, Sori ayé. O de, o mu 'wa-rere wa, Alejo Olore; Gba t'o ba r'ọkan irẹlẹ, Lati ma gbe. Tirẹ l'ohun jẹjẹ t'a ń gbọ, Ohun kẹlẹkẹlẹ; Ti n gbaniwi, ti n l'ẹru lo, Ti n sọ t'ọrun. Gbogbo iwa-rere t'a n hu, Gbogbo isẹgun wa; Gbogbo ero iwa-mimọ; Tirẹ ni wọn. Ẹmi Mimọ Olutunu, F'iyọnu bẹ wa wo; Jọ, s'ọkan wa n'ibugbe Rẹ, K'o yẹ fun Ọ. AMIN
Hymn 387 – Olurapada ikehin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia