Hymn 385 – EMI Mimo 'Daba orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EMI Mimo 'Daba orun" (C&S Hymn #385, Yoruba). ẸMI Mimọ 'Daba ọrun, Wa mu itunu sọkalẹ, Se Ọga at'Olutọ wa, Ma pẹlu…
ẸMI Mimọ 'Daba ọrun, Wa mu itunu sọkalẹ, Se Ọga at'Olutọ wa, Ma pẹlu gbogbo ero wa. Jọ, fi otitọ Rẹ han wa, K'a le fẹ k'a si m'ọna Rẹ, Gbin ifẹ totọ s'ọkan wa, K'a ma le pada lẹhin Rẹ. Mu wa k'a tọ ọna mimọ; T'a le gba d'ọdọ Ọlọrun; Mu wa to Krist, Ọna Iye, Ma jẹ ki awa sina lọ. Mu wa t'Ọlọrun 'sinmi wa, K'a le ma ba gbe titi lai; Tọ wa wa s'ọrun, k'a le n'ipin, L'ọwọ ọtun Ọlọrun wa. AMIN
Hymn 385 – EMI Mimo 'Daba orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia