Hymn 384 – EMI 'bukun ti a n sin | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EMI 'bukun ti a n sin" (C&S Hymn #384, Yoruba). ẸMI 'bukun ti a ń sin, Pẹlu baba at'Ọrọ, Ọlọrun ayérayé; Ẹmi Mimọ, gbọ…
ẸMI 'bukun ti a ń sin, Pẹlu baba at'Ọrọ, Ọlọrun ayérayé; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Ẹmi Mimọ 'Daba ọrun, Iri ti ń sẹ lat'oke, Ẹmi 'ye at'ina 'fẹ, Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Isun ipa at'imọ, Ọgbọn at'iwa mimọ, Oye, imọran, eru; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Isun ifẹ, alafia, Suru, ibisi 'gbagbọ, 'Reti, ayọ ti ki tan; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Ẹmi af'ọna han ni, Ẹmi ti ń mu 'mọlẹ wa, Ẹmi agbara gbogbo; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. 'Wọ t'o mu Wundia bi, Ẹni t'ọrun t'ayé mbọ, T'a ran lati tun wa bi, Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. 'Wọ ti Jesu t'oke ran, Wa tu eniyan Rẹ ninu, Ki wọn ma ba nikan wa, Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. 'Wọ t'o ń f'ore kun Ijọ, T'o ń fi ifẹ Baba han, T'O ń mu k'o ma ri Jesu; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. F'ẹbun meje Rẹ fun ni, Ọgbọn lati m'Ọlọrun, Ipa lati ko ọta: Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Pa ẹsẹ run lọkan wa, Tọ ifẹ wa si ọna, 'Gba ba n sẹ Ọ, mu sùúrù; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Gbe wa dide b'a subú, Ati nigba idanwo, Sa pe wa pada pẹlẹ; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Wa, k'O mu ailera le, F'igboya fun alarẹ, Kọ wa l'ọrọ t'a o sọ; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Wa ran ọkan wa lọwọ, Lati mọ otitọ Rẹ, Ki 'fẹ wa le ma gbona; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. Pa wa mọ l'ọna toro, Ba wa wi nigb'a n sako, Ba wa bẹbẹ l'adura, Ẹmi Mimọ, gbẹ tiwa. Ẹni Mimọ Olufẹ, Wa gbe inu ọkan wa, Ma fi wa silẹ titi; Ẹmi Mimọ, gbọ tiwa. AMIN
Hymn 384 – EMI 'bukun ti a n sin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia