Hymn 383 – EMI Eleda, nipa Re | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EMI Eleda, nipa Re" (C&S Hymn #383, Yoruba). EMI Ẹlẹda, nipa Rẹ, L'a f'ipilẹ ayé sọlẹ, p Ma sai bẹ gbogbo ọkan wo, Fi…

Hymn 383 – EMI Eleda, nipa Re | C&S Yoruba Hymnary
EMI Ẹlẹda, nipa Rẹ, L'a f'ipilẹ ayé sọlẹ, p Ma sai bẹ gbogbo ọkan wo, Fi ayọ Rẹ si ọkan wa; Yọ wa nin' ẹsẹ at'egbe, K'o fi wa se ibugbe Rẹ. Orisun imọlẹ ni Ọ, Ti Baba ti se ileri; Iwọ Ina mimọ ọrun, Fi 'fẹ ọrun kun ọkan wa; Jọ tu ororo mimọ Rẹ, Sori wa bi a ti ń kọrin. Da ọpọ ore-ọfẹ Rẹ, Lat'ọrun sori gbogbo wa; Jẹ k'a gba otitọ Rẹ gbọ, K'a si ma sa ro l'ọkan wa; F'ara Rẹ han wa k'a le ri Baba at'Ọmọ ninu Rẹ. K'a fi ọla ati iyin, Fun Baba Olodumare, K'a yin ọkọ Jesu logo, Ẹni t'o ku lati gba wa; Iyin bakan naa ni fun Ọ, Parakliti Ayérayé.

Hymn 383 – EMI Eleda, nipa Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia