Hymn 380 – Emi Mimo sokale | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Emi Mimo sokale" (C&S Hymn #380, Yoruba). Ẹmi Mimọ sọkalẹ, Ba wa gbe ni ayé yi; Fi ohun ọrun han ni, Si ba ni sin…
Ẹmi Mimọ sọkalẹ, Ba wa gbe ni ayé yi; Fi ohun ọrun han ni, Si ba ni sin Ọlọrun. Ẹsẹ wa ni ọkan wa, Ti a ko le fi silẹ; Agbara wa ko to se, Bi 'Wọ ko ba pẹlu wa. Awa ń fẹ k'ẹsẹ parun, L'ọkan ati l'ara wa; Wa, Ẹmi Mimọ, jọ wa, Ko wẹ gbogbo ẹsẹ nu. Ọlọrun, 'Wọ l'awa ń fẹ, Fi Ẹmi Rẹ naa fun wa; K'a le pa ofin Rẹ mọ, K'a si rin ni ọna Rẹ. AMIN
Hymn 380 – Emi Mimo sokale | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia