Hymn 379 – WA mi si wa, Emi Mimo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA mi si wa, Emi Mimo" (C&S Hymn #379, Yoruba). WA mi si wa, Ẹmi Mimọ , Tan 'na ọrun si ọkan wa: Ẹmi af'ororo yan 'ni,…

Hymn 379 – WA mi si wa, Emi Mimo | C&S Yoruba Hymnary
WA mi si wa, Ẹmi Mimọ , Tan 'na ọrun si ọkan wa: Ẹmi af'ororo yan 'ni, Ti f'ẹmi meje Rẹ fun'ni. Isẹ nla Rẹ at'oke wa: N'itunu, iye, ina ifẹ; F'imọlẹ Rẹ igba gbogbo; Le okunkun ọkan wa lọ. F'ororo ore-ọfẹ Rẹ, Pa oju eri wa ko dan; di L'ọta jina s'ibugbe wa, Ire n' igbe 'biti 'Wọ ń sọ. Kọ wa k'a mọ Baba Ọmọ, Pẹlu Rẹ l'ọkansoso; Titi ayé ainipẹkun, Ni k'eyi ma jẹ orin wa. AMIN

Hymn 379 – WA mi si wa, Emi Mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia