Hymn 378 – EMI orun sọkale wa, gbe 'nu ile yi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EMI orun sọkale wa, gbe 'nu ile yi" (C&S Hymn #378, Yoruba). ẸMI ọrun sọkalẹ wa, gbe 'nu ile yi Ati ẹda alaye mẹrin…

Hymn 378 – EMI orun sọkale wa, gbe 'nu ile yi | C&S Yoruba Hymnary
ẸMI ọrun sọkalẹ wa, gbe 'nu ile yi Ati ẹda alaye mẹrin t'o ń gbe ọrun, Sọkalẹ wa l'agbara yin lat'oke mimọ, Ki adun ayérayé le wa s'ayé wa. Ẹ wa jọsin, ẹ wa jọsin ninu ile yi Ki gbogbo 'dawole wa le yọri si rere. Ki asẹ to sọkalẹ fun Baba nla wa, Solomon n'nu adura rẹ ni iyasimimọ, Ile Ọlọrun ayérayé ti Jerusalem; Ni origun mẹrẹrin to wa layé yi, Le wa dahun s'adura wa ninu ile yi, B'O ti dahun si Baba nla wa Solomon. Baba ọrun, Olore, juba adura wa; Awa ọmọ Rẹ tun de wa bere lọwọ Rẹ; Omii ko san, omi 'pọnju, omii ko ri se; Omii n fẹ 'bukun Ọmọ ko le yin O l'ogo Jọwọ fun wa, jọwọ fun wa ni ibere, K'adura wa 'gba gbogbo le yọri si idahun. F'awọn asiwaju l'ore-ọfẹ kikun; B'O ti f'awọn ti igbani l'aginju ayé yi, Wọn sise ni orukọ Rẹ, wọn gb'ade ogo; F'awọn na l'Ẹmi Mimọ lati gbade ogo; Baba n jiyin, iya n jiyin, Aposteli n yin in; Ati awọn Ẹfanjelist at'Olus'aguntan. K'ibukun ore-ọfẹ kari gbogbo Ijọ, Lati agba titi d'ewe ati awọn Oloye; Mary martyr, Ayab' Esther Awọn Oluranlọwọ iya at'awọn to tun mbọ Baba nla ati Fogo Ọm'ogun 'gbala Ki 'bukun Olodumare, Wa lori akọrin. AMIN

Hymn 378 – EMI orun sọkale wa, gbe 'nu ile yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia