Hymn 377 – EMI orun jare wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EMI orun jare wa" (C&S Hymn #377, Yoruba). ẸMI ọrun jare wa, Wa gunwa s'ọkan wa; Ko se'le rẹ ninu wa, Awa ẹlẹsẹ mbẹ Ọ…

Hymn 377 – EMI orun jare wa | C&S Yoruba Hymnary
ẸMI ọrun jare wa, Wa gunwa s'ọkan wa; Ko se'le rẹ ninu wa, Awa ẹlẹsẹ mbẹ Ọ o. Gba t'a wa n'ile ayé, A kun f'ọpọ asise; T'o ń fa 'danwo wa ba wa, Oluwa ye, jọwọ gba wa o. Nigba ti idanwo ba de, T'ara gbogbo le ko wa; Mura s'ẹsin, gbadura, Jesu yoo si wa gbe ọ leke. Nihin l'ore le tan ọ, Pẹlu baba at'iya, Mura s'ẹsin, p'Oluwa, 'Gbayi ni iwọ mọ Jesu l'ọrẹ. T'ọsan t'oru l'O ń gbọ Gbogbo imikanlẹ rẹ; Ki o to pe O gbọ ọ, Bayi ni ileri Rẹ si ọ. Pe mi loru ati ọsan, Pẹlu ẹmi igbagbọ; Gb'ọkan s'oke s'Oluwa, Jehovah Jire yoo silẹkun. F'ifẹ han k'o si ma se, Isẹ idariji niso; Mu 'gbagbọ pẹlu 'sẹ rẹ, 'Gbayi ni Jesu to gba o la. AMIN

Hymn 377 – EMI orun jare wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia