Hymn 381 – Adaba orun, sokale | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Adaba orun, sokale" (C&S Hymn #381, Yoruba). Adaba ọrun, sọkalẹ, Gbe wa lọ l'apa iyẹ Rẹ; f Ki o si gbe wa ga soke, Ju…
Adaba ọrun, sọkalẹ, Gbe wa lọ l'apa iyẹ Rẹ; f Ki o si gbe wa ga soke, Ju gbogbo ohun ayé lọ. Awa iba le ri itẹ, Olodumare Baba wa, Olugbala joko nibẹ, O gunwa l'awọ bi tiwa. Ẹgbẹ mimọ duro yi ka, Itẹ Agbara wolẹ fun, Ọlọrun han ninu ara, O si tan ogo yi wọn ka. Oluwa, akoko wo ni, Emi o de bugbe loke? T'emi o ma ba wọn wolẹ, Ki n ma sin Ọ, ki n ma kọrin? AMIN
Hymn 381 – Adaba orun, sokale | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia