Hymn 373 – PARADISE! Paradise! | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "PARADISE! Paradise!" (C&S Hymn #373, Yoruba). PARADISE! Paradise! Tani ko fẹ sinmi? Tani ko fẹ 'le ayọ na, Ile…

Hymn 373 – PARADISE! Paradise! | C&S Yoruba Hymnary
PARADISE! Paradise! Tani ko fẹ sinmi? Tani ko fẹ 'le ayọ na, Ile alabukun. Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun. Paradise! Paradise! Ayé ń darugbo lọ, Tani ko si fẹ lọ sinmi, Nib' ifẹ ki tutu? Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun. Paradise! Paradise! Ayé yi ma su mi! Ọkan mi ń fa sọdọ Jesu, Emi ń fẹ r'oju Rẹ. Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun. Paradise! Paradise! Mo fẹ ki n ye dẹsẹ; Mo fẹ ki n wa lọdọ Jesu, Ni ebute mimọ; Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun. Paradise! Paradise! N ko ni duro pe mọ; Nisin yii b'ẹni pe mo ń gbọ; Ohun orin ọrun. Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun. Jesu, Ọba Paradise, Pa mi mọ n'nu 'fẹ Rẹ, Mu mi de ile ayọ na, Nib' isinmi loke Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun. AMIN Nib' awọn olotọ, Wa lai ninu 'mọlẹ, Wọn ń yọ nigba gbogbo, Niwaju Ọlọrun.

Hymn 373 – PARADISE! Paradise! | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia