Hymn 372 – OLORI Ijo t'orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORI Ijo t'orun" (C&S Hymn #372, Yoruba). OLORI Ijọ t'ọrun, L'ayọ l'a wolẹ fun Ọ, K'O to de, Ijọ t'ayé, Yo ma k'orin…

Hymn 372 – OLORI Ijo t'orun | C&S Yoruba Hymnary
OLORI Ijọ t'ọrun, L'ayọ l'a wolẹ fun Ọ, K'O to de, Ijọ t'ayé, Yo ma k'orin bi t'orun A gbe ọkan wa s'oke, Ni 'reti t'o ni 'bukun; Awa kigbe, awa f'iyin, F'Ọlọrun igbala wa. 'Gba t'a wa ninu ipọnju, T'a n kọja ninu ina, Orin ifẹ l'awa o kọ, Ti o ń mu wa sunmọ Ọ, Awa sọpẹ, a si yọ, Ninu ojurere Rẹ; Ifẹ t'o sọ wa di Tirẹ; Y'o se wa ni Tirẹ lai. Iwọ mu awọn eniyan Rẹ, Kọja isan idanwo; A ki o bẹru wahala, 'Tori O wa nitosi; Ayé, ẹsẹ, at'esu, Koju 'ja si wa lasan, L'agbara Rẹ, a o sẹgun, A o si kọ orin Mose. Awa f'igbagbọ r'ogo, T'O tun ń fẹ fi wa si: A kẹgan ayé 'tori, Ere nla iwaju wa, Bi O ba si ka wa yẹ, Awa pẹlu Stefen' t'o ku, Y'o ri Ọ bi O ti duro, Lati pe wa lọ s'ọrun. AMIN

Hymn 372 – OLORI Ijo t'orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia