Hymn 371 – OLODUMARE awa n fe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLODUMARE awa n fe" (C&S Hymn #371, Yoruba). OLODUMARE awa ń fẹ, De 'bute wura didan, Ilu didan t'o si dara, Lẹba itẹ…
OLODUMARE awa ń fẹ, De 'bute wura didan, Ilu didan t'o si dara, Lẹba itẹ Ọlọrun. Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn. Mu wa de Ilu ayọ na Nibi ti Olugbala wa, Oru at' ọsan ko si n'bẹ, Kristi ni imọlẹ wọn Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn. Odi at'Ile Mimọ na, Jẹ wura didan ati pearl, Odo didan, Odo Mimọ, O mọ gara bi Kristal. Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn. Jerusalem Ilu ayọ, 'Rohin Ogo Rẹ ti pọ to! Odi pearli ita wura, Ni Jesu Ọba gbe gunwa. Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn. Aposteli ati Martyr, Baba nla mejila pẹlu, Ẹgbẹ Mary, Ẹgbẹ Matha, Wọn yin Messaiah wọn. Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn. Jerusalem ilu ayọ, 'Rohin Ogo Rẹ ti pọ to! Ilu t'Angẹli Mimọ wa, Wọn ń kọrin s'Ọba wọn. Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn. AMIN Baba jẹ k'awa le de 'bẹ, Ilu Ogo, Ilu to dara didan, K'a le b'awọn k'alleluyah, Orin iyin s'Ọba wọn.
Hymn 371 – OLODUMARE awa n fe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia