Hymn 370 – LEHIN aye buburu yi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "LEHIN aye buburu yi" (C&S Hymn #370, Yoruba). LẸHIN ayé buburu yi, Ayé ẹkun oun osi yi, Ibi rere kan wa, Ayipada ko si…

Hymn 370 – LEHIN aye buburu yi | C&S Yoruba Hymnary
LẸHIN ayé buburu yi, Ayé ẹkun oun osi yi, Ibi rere kan wa, Ayipada ko si nibẹ, Ko s'oru af'ọsan titi, Wi mi, 'wọ o wa nibẹ? 'Lẹkun ogo rẹ ti m'ẹsẹ, Ohun eri ko le wọ'bẹ, Lati b'ẹwa rẹ jẹ, L'ebute daradara ni, A ko ni gburo egun mọ, Wi mi, 'wọ o wa nibẹ? Tani o de 'bẹ? Onirẹlẹ, To f'ibẹru sin Oluwa, T' wọn ko nani ayé; Awọn t'a f'Ẹmi Mimọ tọ, Awọn t'o n rin lọ'na toro, Awọn ni o wa nibẹ. AMIN

Hymn 370 – LEHIN aye buburu yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia