Hymn 366 – ILE 'bukun kan wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ILE 'bukun kan wa" (C&S Hymn #366, Yoruba). ILE 'bukun kan wa, Lẹhin ayé wa yi, Wahala, irora, At'ẹkun ki de'bẹ,…

Hymn 366 – ILE 'bukun kan wa | C&S Yoruba Hymnary
ILE 'bukun kan wa, Lẹhin ayé wa yi, Wahala, irora, At'ẹkun ki de'bẹ, Igbagbọ y'o dopin, A o de 'reti l'ade, Imọlẹ ailopin, Ni gbogbo ibẹ jẹ. Ilẹ kan si tun mbẹ, Ilẹ alafia, Awọn Angel rere, N kọrin n'nu rẹ lailai, Y'itẹ ogo Rẹ ka, L'awọn ẹgbẹ mimọ, N wolẹ, wọn n tẹriba, F'Ẹni Mẹtalọkan. Ayọ wọn ti pọ to! Awọn to ri Jesu, Nibi t'o gbe gunwa, T'a si n fi ogo fun; Wọn n kọrin iyin Rẹ, Ati t'isẹgun Rẹ, Wọn ko dẹkun rohin, Ohun nla t'o ti se. W'oke, ẹyin mimọ, Ẹ le ibẹru lọ; Ọna hiha kan naa, L'Olugbala ti gba; Ẹ fi suru duro, Fun igba diẹ sa, T'ẹrin-t'ẹrin l'Oun o Fi gba yin sọdọ rẹ. AMIN

Hymn 366 – ILE 'bukun kan wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia