Hymn 365 – ILE ayo kan wa l'oke | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ILE ayo kan wa l'oke" (C&S Hymn #365, Yoruba). ILE ayọ kan wa l'oke, Ti o n dan ti o si l'ẹwa, Ayọ ibẹ ki si d'opin,…

Hymn 365 – ILE ayo kan wa l'oke | C&S Yoruba Hymnary
ILE ayọ kan wa l'oke, Ti o n dan ti o si l'ẹwa, Ayọ ibẹ ki si d'opin, L'ọsan tabi l'oru; Awọn Angẹli n kọrin, Y'itẹ Mimọ na ka, Nigba wo la o ri Ọ, Ile to dara julọ. A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l'ogo julọ. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ jẹ k'a yin Oluwa, Fun idasi wa lọjọ oni, Iyin fun Mẹtalọkan; Se ranti p'Oluwa mbọ, Lati ko wa lọ sile, Nigba wo la o ri Ọ, Ile t'o dara julọ. A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l'ogo julọ. Kikankikan l'Oluwa n pe, Ẹda ko si mira; Ikore si n fẹ ka, Ẹ jẹ k'a sa fun ẹsẹ; Ki Jesu le wẹ wa mọ, Yẹ fun 'le nla l'oke, Nigba wo la o ri Ọ, Ile t'o dara julọ. A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l'ogo julọ. Awọn to ti jagun kọja, Wọn n wo wa bi a ti n ja, Wọn mba Ọdaguntan k'ẹgbẹ, Ọba lo si jẹ fun wọn; Ibanujẹ ko si n'ibẹ, Ninu ile didan na; Nigba wo la o ri Ọ, Ile to dara julọ. A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l'ogo julọ. Iwọ ki yoo jijakadi, K'o ba Olugbala jọba, Nibi Kérúbù Séráfù, Yi itẹ Olugbala ka, Ibugbe Olugbala, T'a o ma sin titi; Nigba wo la o ri Ọ, Ile to dara julọ A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l'ogo julọ. Nigba t'o ba d'ọjọ 'kẹhin, Ti a o si de 'jọba Rẹ, K'a gbọ ohun ayọ yi pe, Bo s'ayọ Oluwa rẹ, Kérúbù, Séráfù, yọ Ẹ gb'ade iye yin; Nigba wo la o ri Ọ, Ile to dara julọ. A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l' ogo julọ. AMIN A! Ile didan, A! Ile didan, Ile Olugbala, Ile to l' ogo julọ.

Hymn 365 – ILE ayo kan wa l'oke | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia