Hymn 367 – WA k'a da m'awon ore wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA k'a da m'awon ore wa" (C&S Hymn #367, Yoruba). WA k'a da m'awọn ọrẹ wa, Ti wọn ti jere na; N'ifẹ k'a f'ọkan ba wọn…

Hymn 367 – WA k'a da m'awon ore wa | C&S Yoruba Hymnary
WA k'a da m'awọn ọrẹ wa, Ti wọn ti jere na; N'ifẹ k'a f'ọkan ba wọn lọ, S'ode ọrun lọhun. K'awọn t'ayé dorin wọn mọ, T'awọn to lọ s'ogo; Awa l'ayé, awọn l'ọrun, Ọkan ni gbogbo wa. Idile kan n'nu Krist' ni wa, Ajọ kan l'a si jẹ; Isan omi kan lo ya wa, Isan omi iku. Ẹgbẹ ogun kan t'Ọlọrun, Asẹ Rẹ l'a si n se; Apakan ti w'ọdo na ja; Apakan n wọ lọwọ! Ẹmi wa fẹrẹ dapọ na, Y'o gb'Ade bi tiwọn, A o yọ 's'ami Balogun wa, Lati gbọ ipe Rẹ. Jesu, sọ wa, s'amọna wa, Gba t'onikọ ba de; Oluwa, pin omi meji, Mu wa gunlẹ l'ayọ. AMIN

Hymn 367 – WA k'a da m'awon ore wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia