Hymn 363 – EYIN wo ni tempili Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN wo ni tempili Re" (C&S Hymn #363, Yoruba). ẸYIN wo ni tempili Rẹ, Oluwa t'a ti ń reti; Woli 'gbani ti sọ tẹlẹ;…
ẸYIN wo ni tempili Rẹ, Oluwa t'a ti ń reti; Woli 'gbani ti sọ tẹlẹ; Ọlọrun m'ọrọ Rẹ sẹ; Awọn ti a ti ra pada, Yoo fi ohun kan yin. L'apa wundia iya Rẹ Ẹ sa wo bi O ti sun, Ti awọn alagba ni si ń sin, Ki wọn to ku 'nu 'gbagbọ, Halleluya, Halleluya, W'Ọlọrun Ọga Ogo. f Jesu, nipa ifihan Rẹ, O ti gba iya wa jẹ: Jọ, jẹ ka ri 'gbala nla Rẹ, Mu 'leri Rẹ sẹ si wa, Mu wa lọ sinu ogo Rẹ, Sọdọ Baba Mimọ ni. 'Wọ Alade igbala wa, K'ifẹ Rẹ jẹ orin wa: Jesu, Iwọ l'a fiyin fun, Ni t'ayé t'O ra pada; Pẹlu Baba ati Ẹmi, Oluwa Ẹlẹda wa. AMIN
Hymn 363 – EYIN wo ni tempili Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia