Hymn 362 – E GBO b'awon Angeli ti | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E GBO b'awon Angeli ti" (C&S Hymn #362, Yoruba). Ẹ GBỌ b'awọn Angẹli ti Ń fi Ogo f'Ọlọrun , Ati awọn Olus' Àgùntàn, Ń…

Hymn 362 – E GBO b'awon Angeli ti | C&S Yoruba Hymnary
Ẹ GBỌ b'awọn Angẹli ti Ń fi Ogo f'Ọlọrun , Ati awọn Olus' Àgùntàn, Ń fi'yin fun Un. Gbogbo ogun ọrun pẹlu, Agba mejila, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ń fi'yin fun Un. Ọkẹ meje at'ẹgbaaji, Awọn Agba woli, Awọn t'o ń fẹ l'Olugbala, Ń fi'yin fun Un. Gbogb' Ogun ọrun, ẹ ho ye Ayé gbọ iro naa, Imisi Ẹmi ba le wa; Awa yin! N'tori naa awa Kérúbù, Ati Séráfù, Ninu aginju ayé yi, Ń yin Baba. Ogo fun Baba Olore, Ogo f'Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Loke Ọrun. AMIN

Hymn 362 – E GBO b'awon Angeli ti | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia