Hymn 361 – JERUSALEM t'orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JERUSALEM t'orun" (C&S Hymn #361, Yoruba). JERUSALEM t'ọrun, Orin mi, ilu mi! Ile mi bi mba ku, Ẹkun ibukun mi; Ibi…

Hymn 361 – JERUSALEM t'orun | C&S Yoruba Hymnary
JERUSALEM t'ọrun, Orin mi, ilu mi! Ile mi bi mba ku, Ẹkun ibukun mi; Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? Odi rẹ, ilu mi, L'a fi pearl se l'ọsọ; 'Lẹkun rẹ ń dan fun 'yin, Wura ni ita rẹ! Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? Orun ki ran nibẹ, Bẹni ko s'osupa; A ko wa iwọnyi; Krist n'imọlẹ ibẹ. Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? Nibẹ l'Ọba mi wa, T'a da l'ẹbi l'ayé; Angẹli ń kọrin fun, Wọn si ń tẹriba fun. Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? Patriark 'gbani, Par' ayọ wọn nibẹ; Awọn woli, wọn wo, Ọmọ alade wọn. Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? Nibẹ ni mo le ri, Awọn aposteli; At'awọn akọrin, Ti ń lu harpu wura. Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? Ni agbala wọnni, Ni awọn Martyr wa; Wọn wọ asọ ala, Ogo bo ọgbẹ wọn. Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? p T'emi yi sa su mi, Ti mo n gb'agọ Kedar! Ko si 'ru yi loke; cr Nibẹ ni mo fẹ lọ. Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi? AMIN Ibi ayọ! Nigba wo ni, N ó r'oju rẹ, Ọlọrun mi?

Hymn 361 – JERUSALEM t'orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia