Hymn 359 – E JUBA Olorun wa, Jah | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E JUBA Olorun wa, Jah" (C&S Hymn #359, Yoruba). Ẹ JUBA Ọlọrun wa, Jah, Ọba onifẹ julọ, Olubori, Ajabori, Ọba Ọrun oun…
Ẹ JUBA Ọlọrun wa, Jah, Ọba onifẹ julọ, Olubori, Ajabori, Ọba Ọrun oun Ayé. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Bayi l'o dawọn ẹda Rẹ, B'o ti wu Ọ l'o da wọn, Awimayẹhun sa ni Ọ, Awamaridi ni Ọ. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Nibi t'ọna ko ti si ri, Nibẹ ni 'joko mi wa Nip'agbara at'asa mi, Larin awọn eniyan mi. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; A ha ri ẹni le pada, Gba mba n sisẹ ogo mi, Awọn Angel' to l'agbara, Wọn ko jẹ dan eyi wo. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Lusifa t'o l'agbara ju, Gbogbo awọn Angel' lọ, O f'ọwọ pa 'da mi loju, O si d'ẹni ifibu Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ẹgbẹgbẹrun ogun ọrun, L'o n sọ ti agbara mi, Ogo, Ọla ati 'pa mi, Wọn n juba Agbara mi. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Sibẹ Emi ko yan eyi, T'o ga julọ ninu wọn, Sugbọn Maikel t'o kere ju, Ni Mo gbega ninu wọn. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Agbara ninu Agbara, Ogo, Ọla at'ipa, Tẹru, tẹru, tifẹtifẹ, Ifẹ si l'orukọ mi Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; AMIN Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni;
Hymn 359 – E JUBA Olorun wa, Jah | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia