Hymn 358 – BABA to da orun meje | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA to da orun meje" (C&S Hymn #358, Yoruba). BABA to da ọrun meje, Ati'lẹ meje pẹlu, Ayé lo se ẹkẹdogun, Iyin ni…
BABA to da ọrun meje, Ati'lẹ meje pẹlu, Ayé lo se ẹkẹdogun, Iyin ni f'orukọ Rẹ. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. Orun, Osupa, Irawọ, Awọn ni 'mọlẹ ayé; Okuta Oniyebiye; Awọn ni 'mọlẹ 'salẹ. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. Abo Oluwa Onikẹ, L'awa Ẹgbẹ bora mọ; Ko s'ohun 'bi to le se wa, Lagbara Mẹtalọkan. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. Ẹni loyun a bimọ la, Agan a t'ọwọ b'osun; Ọlọmọ ko ni padanu, Iku ko ri wa gbe se. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. Ko s' ẹni ti n ri'di okun, A ki n ri'di ọlọsa, Baba to da ọrun oun ayé, Ma jẹ k'ayé r'idi mi. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. Awọn Agbara Ẹmi meje, Ta fi wọ HOLY MICHAEL To si fi sẹgun Lusifa, Lọjọ ogun Ọlọrun, Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan to gunwa, Jọwọ ko gbọ adura wa, Larin Ẹgbẹ Séráfù. Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni. AMIN Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni; Ijinlẹ lọrọ na, Awamaridi si ni.
Hymn 358 – BABA to da orun meje | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia