Hymn 357 – 'LAI lodo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'LAI lodo Oluwa" (C&S Hymn #357, Yoruba). 'LAI lọdọ Oluwa! Amin, bẹni ko ri, Iye wa ninu ọrọ na, Aiku ni titi lai,…

Hymn 357 – 'LAI lodo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
'LAI lọdọ Oluwa! Amin, bẹni ko ri, Iye wa ninu ọrọ na, Aiku ni titi lai, Nihin ninu ara, Mo sako jina si; Sibẹ, alalẹ ni mo n fi, Ọjọ kan sun mọle! Ile Baba loke, Ile ọkan mi ni; Emi n fi oju igbagbọ, Wo 'bode wura rẹ! Ọkan mi n fa pupọ, S'ile na ti mo fẹ, Ile didan t'awọn mimọ, Jerusalem t'ọrun Awọsanmọ dide, Gbogbo ero mi pin; Bi adaba Noa, mo n fo Larin iji lile, Sugbọn sanmọ kuro, Iji si rekọja, Ayọ ati alafia, Si gba ọkan mi kan. Loorọ ati l'alẹ, Lọsan ati l'oru, Mo n gbọ orin ọrun, bori Rudurudu ayé; Ọrọ ajinde ni, Hiho isẹgun ni Lẹkan si, ―Lai lọd' Oluwa Amin, bẹni k'o ri.

Hymn 357 – 'LAI lodo Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia