Hymn 356 – ALABUKUN n'nu Jesu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ALABUKUN n'nu Jesu" (C&S Hymn #356, Yoruba). ALABUKUN n'nu Jesu, Ni awọn ọm'Ọlọrun, Ti a f'ẹjẹ Rẹ ra, Lati' inu iku…

Hymn 356 – ALABUKUN n'nu Jesu | C&S Yoruba Hymnary
ALABUKUN n'nu Jesu, Ni awọn ọm'Ọlọrun, Ti a f'ẹjẹ Rẹ ra, Lati' inu iku s'iye; A ba jẹ ka wa mọ wọn, L'ayé yi, ati l'ọrun. Awọn ti o da l'are; Nipa ore-ọfẹ Rẹ; A wẹ gbogbo ẹsẹ wọn, Wọn o bọ lọjọ 'dajọ,,,, A ba jẹ ka wa mọ wọn, L'ayé yi, ati l'ọrun. Wọn s'eso ore-ọfẹ; Ninu isẹ ododo, Irira l'ẹsẹ si wọn; Ọr'-Ọlọrun n gbe 'nu wọn; A ba jẹ ka wa mọ wọn, L'ayé yi, ati l'ọrun. Nipa Ẹj'Ọdaguntan, Wọn mba Ọlọrun kẹgbẹ, Pẹlu Ọla-nla Jesu, A wọ wọn l'asọ ogo. A ba jẹ ka wa mọ wọn, L'ayé yi, ati l'ọrun. AMIN A ba jẹ ka wa mọ wọn, L'ayé yi, ati l'ọrun.

Hymn 356 – ALABUKUN n'nu Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia