Hymn 355 – NINU ile Baba mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "NINU ile Baba mi" (C&S Hymn #355, Yoruba). NINU ile Baba mi, Ọpọ aye wa nibẹ, 'Bugbe to dara julọ, Wa lọdọ Oluwa,…
NINU ile Baba mi, Ọpọ aye wa nibẹ, 'Bugbe to dara julọ, Wa lọdọ Oluwa, Mura, Mura ) Arakunrin, )2 Tirẹ laye na ) Ainiye ti kọja lọ, Si egbe tabi iye, Jọwọ yan iye loni, Akoko n kọja lọ. Mura, Mura ) Arakunrin, ) 2 K'pe na to dun ) L'eri nla ti Baba se, F'awọn ayanfẹ totọ, Pe nibi t'Oun ba wa; L'awọn na y'o ma gbe. Mura, Mura ) Ọmọ Jesu )2 Fun ileri yi. ) Ọp' ọkan ti kọja lọ, Si egbe tabi iye; Sibẹ ẹlẹsẹ n sawada, Ko ronu ọla rẹ Mura, Mura ) Ọmọ-araye )2 K'anu to kọja ) Jesu Oluwa mbọ wa, Ki se lati tun ku mọ, Mbọ Ọba awọn ọba, Onidajọ aye. Mura, Mura ) Onigbagbọ, )2 Ki 'lẹkun to se. ) AMIN
Hymn 355 – NINU ile Baba mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia