Hymn 354 – F'AWON Ijo ti n sinmi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "F'AWON Ijo ti n sinmi" (C&S Hymn #354, Yoruba). F'AWỌN Ijọ ti n sinmi, Awa Ijọ t'ayé; A f'iyin gbogbo fun Ọ, Jesu…
F'AWỌN Ijọ ti n sinmi, Awa Ijọ t'ayé; A f'iyin gbogbo fun Ọ, Jesu Olubukun; Oluwa, O ti sẹgun, Ki wọn ba le sẹgun, 'Mọlẹ ade ogo wọn, Lat'ọdọ rẹ wa ni. St. Anderu A yin Ọ fun 'ransẹ Rẹ, Ti o ko j'ipe Rẹ, T'o mu arakunrin rẹ, Wa, lati ri Kristi; Pese ọkan wa silẹ K'a s'ọna lọdun yi, K'a m'awọn ara wa wa, Lati ri bibọ Rẹ. St. Thomasi A yin Ọ, fun 'ransẹ Rẹ, T'isiyemeji rẹ, F'ẹsẹ 'gbagbọ wa mulẹ, T'o si fi'fẹ Rẹ han, Oluwa, f'alafia, F'awọn ti n reti Rẹ, Jẹ k'a mọ Ọ lotito, L'eniyan at'Ọlọrun. St. Stefanu A yin Ọ, fun 'ransẹ Rẹ, Ajẹriku 'kini, Ẹni, ninu wahala, T'o n kẹ pe Ọlọrun; Oluwa, b'o ba kan wa, Lati jiya fun Ọ, L'ayé, jẹ k'a jẹri Rẹ, L'ọrun, jẹ k'a gb'ade St. Johanu Onihinrere A yin Ọ, fun 'ransẹ Rẹ, L'erekusu Patmo, A yin Ọ, f'ẹri totọ, Ti o jẹ nipa Rẹ, A yin Ọ fun iran na, Ti o fi han fun wa; A o fi suru duro, K'a le ka wa mọ wọn. Ọjo awọn ọmọ … ti a pa A yin Ọ, f'awọn ewe Ajẹriku mimọ; A si wọn l'ọwọ ogun, Lọ sibi isinmi; Rakieli, ma sọkun mọ, Wọn bọ lọwọ 'rora, F'ọkan ailẹtan fun wa, K'a gb'ade bi tiwọn. Iyipada ti St. paul A yin Ọ, fun imọlẹ, At'ohun lat'ọrun, A si yin Ọ, fun iran, Ti abinuku ri; Ati fun 'yipada rẹ, A fi ogo fun Ọ, Jọ, tan ina Ẹmi Rẹ, Sinu okunkun wa. St. Mattia Oluwa, Iwọ t'o wa Pẹl' awọn t'o pejọ; Iwọ t'o yan Mattia Lati rọpo Juda; A' mbẹ Ọ, gba Ijọ Rẹ Lọwọ eke woli; Rant' ileri Rẹ, Jesu Pẹlu 'jọ Rẹ dopin. St. Marku A yin Ọ fun 'ransẹ Rẹ, T'Iwọ f'agbara fun: Ẹni t'ihinrere Rẹ, Mu orin 'sẹgun dun; Ati n'nu ailera wa, Jọ jẹ agbara wa; Jẹ ka s'eso ninu Rẹ, Iwọ Ajara wa. St. Filippi ati St. Jakọbu A Yin Ọ fun 'ransẹ Rẹ, Filippi amọna, Ati f'arakunrin Rẹ, Se wa l'arakunrin; Masai jẹ k'a le mọ Ọ, Ọna, Iye, Ootọ; K'a doju kọ idanwo, Titi a o fi sẹgun. St. Barnaba A yin Ọ, fun Barnaba, Ẹni t'ifẹ Rẹ mu, K'o ko 'hun ayé silẹ, K'ọ wa ohun ọrun, Bi ayé ti n gbilẹ si, Ran ẹmi Rẹ si wa, Ki itunu Rẹ totọ; Tan bo gbogbo ayé. St. Johanu Baptisti A yin Ọ f'Onibaptis, Asaju Oluwa; Elija totọ ni 'se, Lati tun ọna se, Woli to ga julọ ni, O ri owurọ Rẹ; Se…
Hymn 354 – F'AWON Ijo ti n sinmi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia