Hymn 353 – E WA k'a da orin wa po | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E WA k'a da orin wa po" (C&S Hymn #353, Yoruba). Ẹ WA k'a da orin wa pọ, Mọ t'awọn Angẹli; Ẹgbẹgbẹrun ni ohun wọn,…

Hymn 353 – E WA k'a da orin wa po | C&S Yoruba Hymnary
Ẹ WA k'a da orin wa pọ, Mọ t'awọn Angẹli; Ẹgbẹgbẹrun ni ohun wọn, Ọkan ni ayọ wọn. Wọn n kọrin pe, Ọla-nla yẹ, Ọd'-aguntan t'a pa,‖ K'a gberin pe ―Ọla-nla yẹ, 'Tori O ku fun wa. Jesu, ni O yẹ lati gba, Ọla at'agbara; K'iyin t'ẹnu wa ko le gba, Jẹ Tirẹ, Oluwa. K'awọn t'o wa loke ọrun, At'ilẹ, at'okun; Dapọ lati gb'ogo Rẹ ga, Jumọ yin ọla Rẹ. ff Ki gbogbo ẹda d'ohun pọ, Lati yin orukọ, Ẹni t'o joko lor'itẹ, Ki wọn si wolẹ fun. AMIN

Hymn 353 – E WA k'a da orin wa po | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia