Hymn 352 – ILE ewa wonni, b'o ti dara to | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ILE ewa wonni, b'o ti dara to" (C&S Hymn #352, Yoruba). ILE ẹwa wọnni, b'o ti dara to, Ibugbe Ọlọrun, t'oju ko ti ri;…

Hymn 352 – ILE ewa wonni, b'o ti dara to | C&S Yoruba Hymnary
ILE ẹwa wọnni, b'o ti dara to, Ibugbe Ọlọrun, t'oju ko ti ri; Ta l'o fẹ de ibẹ, lẹhin ayé yi? Ta l'o fẹ k'a wọ oun ni asọ funfun? Awọn wọnni ni, t' o ji nin' orun wọn; Awọn t'o ni 'gbagbọ si nkan t'a ko ri; Awọn t'o k'aniyan wọn l'Olugbala, Awọn ti ko tiju agbelebu Krist. Awọn ti ko nani gbogbo nkan ayé; Awọn t'o le soto de oju iku, Awọn t'o n rubọ ifẹ l'ojojumọ, Awọn ta f'igbala Jesu ra pada. f Itiju ni fun yin, ọm'-ogun Jesu, Ẹyin ara ilu ibugbe ọrun, Kinla! ẹ n fi fere, at'ilu sire; 'Gbat'o ni k'e sisẹ t'o si pe, ẹ ja! B'igbi omi ayé si ti n kọlu wa, Jesu Ọba ogo, sọ si wa leti Adun t'o wa l'ọrun, ilu mimọ ni, Nibi t'isinmi wa lai ati lailai. AMIN

Hymn 352 – ILE ewa wonni, b'o ti dara to | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia