Hymn 351 – OKE kan mbe t'o n dan t'o ga | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OKE kan mbe t'o n dan t'o ga" (C&S Hymn #351, Yoruba). OKE kan mbẹ t'o n dan t'o ga, Nibi t'a m'Ọlọrun, O wa l'okere…
OKE kan mbẹ t'o n dan t'o ga, Nibi t'a m'Ọlọrun, O wa l'okere ni ọrun, Itẹ Ọlọrun ni. Tal' awọn t'o sunmọ ibẹ, Lati wo itẹ Rẹ? Ẹgbarun 'wọn t'o wa nibẹ, Ọmọde bi awa. Olugbala w'ẹsẹ wọn nu, O sọ wọn di mimọ; Wọn f'ọrọ Rẹ, wọn f'ọjọ Rẹ, Wọn fẹ, wọn si ri i. Labẹ ọpọ oku tutu, L'ara wọn sinmi si; Wọn ri 'gbala ọkan wọn he, Laya Olugbala. K'awa k'o rin bi wọn ti n rin; Ipa t'o lọ s'ọrun; Wa idariji Ọlọrun, T'o ti dariji wọn. p Jesu n gbọ irẹlẹ ẹkun, T'o mu ọkan d'ọtun, Lori oke t'o dan, t'o ga; L'awa o ma wo Ọ. AMIN
Hymn 351 – OKE kan mbe t'o n dan t'o ga | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia